Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí.

Jeremiah 28:6 in English

Jeremiah 28:6 · Berean Standard Bible

“Amen!” Jeremiah said. “May the LORD do so! May the LORD fulfill the words you have prophesied, and may He restore the articles of His house and all the exiles back to this place from Babylon.

Context

4Èmi á tún mú ààyè Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Juda ní Babeli,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba Babeli yóò rọrùn.’ ” 5Wòlíì Jeremiah wí fún wòlíì Hananiah ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa. 6Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí. 7Nísinsin yìí, ìwọ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí mo sọ sí etí rẹ àti sí etí gbogbo ènìyàn. 8Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.