Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’

Jeremiah 27:9 in English

Jeremiah 27:9 · Berean Standard Bible

But as for you, do not listen to your prophets, your diviners, your interpreters of dreams, your mediums, or your sorcerers who declare, ‘You will not serve the king of Babylon.’

Context

7Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún. 8“ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀. 9Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’ 10Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé. 11Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.