Jeremiah 27:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.
Jeremiah 27:7 in English
Jeremiah 27:7 · Berean Standard Bible
All nations will serve him and his son and grandson, until the time of his own land comes; then many nations and great kings will enslave him.
Context
5Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi. 6Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀. 7Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún. 8“ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀. 9Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.