Jeremiah 27:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà.
Jeremiah 27:19 in English
Jeremiah 27:19 · Berean Standard Bible
For this is what the LORD of Hosts says about the pillars, the sea, the bases, and the rest of the articles that remain in this city,
Context
17Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro? 18Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 19Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà. 20Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu. 21Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti ní Jerusalẹmu:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.