Jeremiah 27:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.
Jeremiah 27:18 in English
Jeremiah 27:18 · Berean Standard Bible
If they are indeed prophets and the word of the LORD is with them, let them now plead with the LORD of Hosts that the articles remaining in the house of the LORD, in the palace of the king of Judah, and in Jerusalem, not be taken to Babylon.
Context
16Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Babeli,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn. 17Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro? 18Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 19Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà. 20Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.