Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè.

Jeremiah 27:12 in English

Jeremiah 27:12 · Berean Standard Bible

And to Zedekiah king of Judah I spoke the same message: “Put your necks under the yoke of the king of Babylon; serve him and his people, and live!

Context

10Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé. 11Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ” 12Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè. 13Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli? 14Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.