Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘A ó sì fa Sioni tu bí oko Jerusalẹmu yóò di òkìtì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’

Jeremiah 26:18 in English

Jeremiah 26:18 · Berean Standard Bible

“Micah the Moreshite prophesied in the days of Hezekiah king of Judah and told all the people of Judah that this is what the LORD of Hosts says: ‘Zion will be plowed like a field, Jerusalem will become a heap of rubble, and the temple mount a wooded ridge.’*

Context

16Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.” 17Lára àwọn àgbàgbà ilẹ̀ náà sì sún síwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, 18“Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘A ó sì fa Sioni tu bí oko Jerusalẹmu yóò di òkìtì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’ 19Ǹjẹ́ Hesekiah ọba Juda tàbí ẹnikẹ́ni ní Juda pa á bí? Ǹjẹ́ Hesekiah kò bẹ̀rù Olúwa tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ Olúwa kò ha a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.” 20(Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.