Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.”

Jeremiah 26:16 in English

Jeremiah 26:16 · Berean Standard Bible

Then the officials and all the people told the priests and prophets, “This man is not worthy of death, for he has spoken to us in the name of the LORD our God!”

Context

14Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi. 15Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.” 16Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.” 17Lára àwọn àgbàgbà ilẹ̀ náà sì sún síwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, 18“Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘A ó sì fa Sioni tu bí oko Jerusalẹmu yóò di òkìtì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.