Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, “Èmi ni Olúwa.” Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

Jeremiah 24:7 in English

Jeremiah 24:7 · Berean Standard Bible

I will give them a heart to know Me, that I am the LORD. They will be My people, and I will be their God, for they will return to Me with all their heart.

Context

5“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjèjì láti Juda sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea. 6Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere, Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu. 7Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, “Èmi ni Olúwa.” Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. 8“ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Sedekiah ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jerusalẹmu, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Ejibiti. 9Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ẹni ìfibú àti ẹni òwe, ẹni ẹ̀sín, àti ẹni ẹ̀gàn ní ibi gbogbo tí Èmi ó lé wọn sí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.