Jeremiah 2:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn kìnnìún ké ramúramù; wọ́n sì ń bú mọ́ wọn. Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò; ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.
Jeremiah 2:15 in English
Jeremiah 2:15 · Berean Standard Bible
The young lions have roared at him; they have growled with a loud voice. They have laid waste his land; his cities lie in ruins, without inhabitant.
Context
13“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì,
wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Èmi orísun omi ìyè,
wọ́n sì ti ṣe àmù,
àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró. 14Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí?
Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun? 15Àwọn kìnnìún ké ramúramù;
wọ́n sì ń bú mọ́ wọn.
Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò;
ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀. 16Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi
wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ. 17Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín
nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀
nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.