Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: “ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’

Jeremiah 15:2 in English

Jeremiah 15:2 · Berean Standard Bible

If they ask you, ‘Where shall we go?’ you are to tell them that this is what the LORD says: ‘Those destined for death, to death; those destined for the sword, to the sword;* those destined for famine, to famine; and those destined for captivity, to captivity.’

Context

1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ! 2Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: “ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’ 3“Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun. 4N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.