Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n, àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi, nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.

Jeremiah 15:16 in English

Jeremiah 15:16 · Berean Standard Bible

Your words were found, and I ate them. Your words became my joy and my heart’s delight. For I bear Your name, O LORD God of Hosts.

Context

14Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.” 15Ó yé ọ, ìwọ Olúwa; rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi. Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ; nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ. 16Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n, àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi, nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára. 17Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn, n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi. 18Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.