Jeremiah 15:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
Jeremiah 15:13 in English
Jeremiah 15:13 · Berean Standard Bible
Your wealth and your treasures I will give up as plunder, without charge for all your sins within all your borders.
Context
11Olúwa sọ pé,
“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó;
dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ
nígbà ibi àti ìpọ́njú. 12“Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin
irin láti àríwá tàbí idẹ? 13“Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ
ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba
nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ
jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ. 14Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ
ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú
mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.” 15Ó yé ọ, ìwọ Olúwa;
rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi.
Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi.
Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ;
nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.