Jeremiah 15:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi, ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà! Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
Jeremiah 15:10 in English
Jeremiah 15:10 · Berean Standard Bible
Woe to me, my mother, that you have borne me, a man of strife and conflict in all the land. I have neither lent nor borrowed, yet everyone curses me.
Context
8Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju
yanrìn Òkun lọ.
Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun
kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn.
Lójijì ni èmi yóò mú
ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn. 9Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú,
yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn.
Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan,
yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù.
Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú
àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”
ni Olúwa wí. 10Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi,
ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà!
Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni,
síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré. 11Olúwa sọ pé,
“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó;
dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ
nígbà ibi àti ìpọ́njú. 12“Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin
irin láti àríwá tàbí idẹ?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.