Jeremiah 14:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Juda káàánú, àwọn ìlú rẹ̀ kérora wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn, igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
Jeremiah 14:2 in English
Jeremiah 14:2 · Berean Standard Bible
“Judah mourns and her gates languish. Her people wail for the land, and a cry goes up from Jerusalem.
Context
1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn: 2“Juda káàánú,
àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu. 3Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
wọ́n sì bo orí wọn. 4Ilẹ̀ náà sán
nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
wọ́n sì bo orí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.