Jeremiah 14:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”
Jeremiah 14:10 in English
Jeremiah 14:10 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says about this people: “Truly they love to wander; they have not restrained their feet. So the LORD does not accept them; He will now remember their guilt and call their sins to account.”
Context
8Ìrètí Israẹli;
ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré? 9Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,
bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?
Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,
orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;
má ṣe fi wá sílẹ̀. 10Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:
“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;
wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.
Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;
yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,
yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.” 11Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 12Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.