Jeremiah 12:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?
Jeremiah 12:1 in English
Jeremiah 12:1 · Berean Standard Bible
Righteous are You, O LORD, when I plead before You. Yet about Your judgments I wish to contend with You: Why does the way of the wicked prosper? Why do all the faithless live at ease?
Context
1Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà,
nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá.
Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ.
Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé?
Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn? 2Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀,
wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso.
Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn,
o jìnnà sí ọkàn wọn. 3Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa,
o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò.
Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa.
Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.