Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọbi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀síwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé wa sórí wọn.’ ”

Jeremiah 11:8 in English

Jeremiah 11:8 · Berean Standard Bible

Yet they would not obey or incline their ears, but each one followed the stubbornness of his evil heart. So I brought on them all the curses of this covenant I had commanded them to follow but they did not keep.”

Context

6Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda àti ní gbogbo òpópónà ìgboro Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì se wọn. 7Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.” 8Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọbi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀síwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé wa sórí wọn.’ ” 9Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrín àwọn ará Juda àti àwọn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. 10Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí wọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti ba májẹ̀mú tí mo dá pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.