Jeremiah 1:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.”
Jeremiah 1:5 in English
Jeremiah 1:5 · Berean Standard Bible
“Before I formed you in the womb I knew you, and before you were born I set you apart and appointed you as a prophet to the nations.”
Context
3àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn. 4Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé, 5“Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,
kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.
Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” 6Mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.” 7Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.