Onidajọ 9:28
Judges 9:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gaali ọmọ Ebedi dáhùn pé, “Ta ni Abimeleki tàbí ta ni Ṣekemu tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubbaali kọ́ ní ṣe tàbí Sebulu kọ́ ní igbákejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hamori baba àwọn ará Ṣekemu, èéṣe tí a ó fi sin Abimeleki?
Judges 9:28 in English
Judges 9:28 · Berean Standard Bible
Then Gaal son of Ebed said, “Who is Abimelech, and who is Shechem, that we should serve him? Is he not the son of Jerubbaal, and is not Zebul his officer? You are to serve the men of Hamor, the father of Shechem. Why should we serve Abimelech?
Context
26Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣekemu, àwọn ará Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé wọn, wọ́n sì fi inú tán wọn. 27Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èso àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èso àjàrà náà, wọ́n sì ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Abimeleki ré. 28Gaali ọmọ Ebedi dáhùn pé, “Ta ni Abimeleki tàbí ta ni Ṣekemu tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubbaali kọ́ ní ṣe tàbí Sebulu kọ́ ní igbákejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hamori baba àwọn ará Ṣekemu, èéṣe tí a ó fi sin Abimeleki? 29Ìbá se pé àwọn ènìyàn yìí wà ní abẹ́ ìṣàkóso mi ni! Èmi ìbá bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín. Èmi yóò wí fún Abimeleki pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ” 30Nígbà tí Sebulu, alákòóso ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali ọmọ Ebedi sọ, inú bí i gidigidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.