Onidajọ 9:17
Judges 9:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani;
Judges 9:17 in English
Judges 9:17 · Berean Standard Bible
for my father fought for you and risked his life to deliver you from the hand of Midian,
Context
15“Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí olóòtítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àsálà sí abẹ́ ibòòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi kedari àti ti Lebanoni run!’ 16“Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Abimeleki jẹ ọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un. 17Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani; 18ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Abimeleki ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀ jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn Ṣekemu nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín. 19Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Abimeleki kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.