Native Bible

Judges 7:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gideoni àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀.

Judges 7:19 in English

Judges 7:19 · Berean Standard Bible

Gideon and the hundred men with him reached the outskirts of the camp at the beginning of the middle watch, just after the changing of the guard. They blew their horns and broke the jars that were in their hands.

Context

17Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe. 18Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, ‘Fún Olúwa àti fún Gideoni.’ ” 19Gideoni àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀. 20Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn fìtílà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hé è pé, “Idà kan fún Olúwa àti fún Gideoni!” 21Nígbà tí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan dúró ní ipò rẹ̀ yí ibùdó àwọn Midiani ká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun Midiani ń sá káàkiri, wọ́n ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sálọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.