Onidajọ 7:18
Judges 7:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, ‘Fún Olúwa àti fún Gideoni.’ ”
Judges 7:18 in English
Judges 7:18 · Berean Standard Bible
When I and all who are with me blow our horns, then you are also to blow your horns from all around the camp and shout, ‘For the LORD and for Gideon!’”
Context
16Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà. 17Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe. 18Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, ‘Fún Olúwa àti fún Gideoni.’ ” 19Gideoni àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀. 20Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn fìtílà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hé è pé, “Idà kan fún Olúwa àti fún Gideoni!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.