Native Bible

Judges 6:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gideoni wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí—

Judges 6:36 in English

Judges 6:36 · Berean Standard Bible

Then Gideon said to God, “If You are going to save Israel by my hand, as You have said,

Context

34Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gideoni, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Abieseri láti tẹ̀lé òun. 35Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Manase já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Aṣeri, Sebuluni àti Naftali gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn. 36Gideoni wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí— 37kíyèsi, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá sẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yòókù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.” 38Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Gideoni jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì fún irun àgùntàn náà, ọpọ́n omi kan sì kún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.