Onidajọ 6:30
Judges 6:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.”
Judges 6:30 in English
Judges 6:30 · Berean Standard Bible
Then the men of the city said to Joash, “Bring out your son. He must die, because he has torn down Baal’s altar and cut down the Asherah pole beside it.”
Context
28Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Baali àti pé a ti bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ. 29Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?”
Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” 30Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.” 31Ṣùgbọ́n Joaṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Baali bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Baali bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.” 32Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gideoni ní “Jerubbaali” wí pé, “Jẹ́ kí Baali bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.