Native Bible

Judges 6:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo wí fún un yín pé, ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín; ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.”

Judges 6:10 in English

Judges 6:10 · Berean Standard Bible

And I said to you: ‘I am the LORD your God. You must not fear * the gods of the Amorites, in whose land you dwell.’ But you did not obey Me.”

Context

8Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: mo mú yín gòkè ti Ejibiti wá, láti oko ẹrú. 9Mo gbà yín kúrò nínú agbára Ejibiti àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín. 10Mo wí fún un yín pé, ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín; ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.” 11Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù Ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani. 12Nígbà tí angẹli Olúwa fi ara han Gideoni, ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.