Onidajọ 5:13
Judges 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ; àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára.
Judges 5:13 in English
Judges 5:13 · Berean Standard Bible
Then the survivors came down to the nobles; the people of the LORD came down to me against the mighty.
Context
11ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.
Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa,
àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli.
“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa
sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè. 12‘Jí, jí, Debora!
Jí, jí, kọ orin dìde!
Dìde ìwọ Baraki!
Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’ 13“Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ;
àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára. 14Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki;
Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.
Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá,
láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́. 15Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora;
bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki,
wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.
Ní ipadò Reubeni
ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.