Onidajọ 3:29
Judges 3:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.
Judges 3:29 in English
Judges 3:29 · Berean Standard Bible
At that time they struck down about ten thousand Moabites, all robust and valiant men. Not one of them escaped.
Context
27Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn. 28Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. 29Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà. 30Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún. 31Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ẹgbẹ̀ta (600) Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.