Onidajọ 20:46
Judges 20:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun.
Judges 20:46 in English
Judges 20:46 · Berean Standard Bible
That day 25,000 Benjamite swordsmen fell, all men of valor.
Context
44Ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun. 45Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin ṣubú. 46Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. 47Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin. 48Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.