Native Bible

Judges 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.

Judges 2:7 in English

Judges 2:7 · Berean Standard Bible

And the people served the LORD throughout the days of Joshua and of the elders who outlived him, who had seen all the great works that the LORD had done for Israel.

Context

5wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rú ẹbọ sí Olúwa níbẹ̀. 6Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn. 7Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli. 8Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún. 9Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Timnati-Hereki ní ilẹ̀ òkè Efraimu ní àríwá òkè Gaaṣi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.