Native Bible

Judges 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn.

Judges 2:6 in English

Judges 2:6 · Berean Standard Bible

After Joshua had dismissed the people, the Israelites went out to take possession of the land, each to his own inheritance.

Context

4Bí angẹli Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sọkún kíkorò, 5wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rú ẹbọ sí Olúwa níbẹ̀. 6Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn. 7Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli. 8Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.