Onidajọ 19:4
Judges 19:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.
Judges 19:4 in English
Judges 19:4 · Berean Standard Bible
His father-in-law, the girl’s father, persuaded him to stay, so he remained with him three days, eating, drinking, and lodging there.
Context
2Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà sì ṣe panṣágà sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda, ó sì wà ní ibẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́rin, 3ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á. 4Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀. 5Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.” 6Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.