Onidajọ 19:21
Judges 19:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹsẹ̀ wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu.
Judges 19:21 in English
Judges 19:21 · Berean Standard Bible
So he brought him to his house and fed his donkeys. And they washed their feet and ate and drank.
Context
19Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ—èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.” 20Ọkùnrin arúgbó náà sì wí pé. “Àlàáfíà fún ọ, bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò pèsè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ní ìgboro.” 21Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹsẹ̀ wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu. 22Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Beliali kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kùn; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.” 23Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.