Native Bible

Judges 17:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu

Judges 17:1 in English

Judges 17:1 · Berean Standard Bible

Now a man named Micah from the hill country of Ephraim

Context

1Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu 2sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣẹ́ èpè. Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.” Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí Olúwa bùkún ọ ọmọ mi!” 3Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.