Onidajọ 12:7
Judges 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi.
Judges 12:7 in English
Judges 12:7 · Berean Standard Bible
Jephthah judged Israel six years, and when he died, he was buried in one of the cities of Gilead.*
Context
5Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” 6wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣibolẹti.’ ” Tí ó bá ní, “Sibolẹti,” torí pé kò ní mọ̀ ọ́n pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) ọkùnrin. 7Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi. 8Lẹ́yìn Jefta, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. 9Ó ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ibsani ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.