Native Bible

Judges 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

Judges 1:14 in English

Judges 1:14 · Berean Standard Bible

One day Acsah came to Othniel and urged him * to ask her father for a field. When she got off her donkey, Caleb asked her, “What do you desire?”

Context

12Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 13Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó. 14Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?” 15Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀. 16Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.