Native Bible

James 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni.

James 3:15 in English

James 3:15 · Berean Standard Bible

Such wisdom does not come from above, but is earthly, unspiritual, demonic.

Context

13Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà. 17Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.