Native Bible

James 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù.

James 3:12 in English

James 3:12 · Berean Standard Bible

My brothers, can a fig tree grow olives, or a grapevine bear figs? Neither can a salt spring * produce fresh water.

Context

10Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. 11Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? 12Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù. 13Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.