Native Bible

James 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí?

James 3:11 in English

James 3:11 · Berean Standard Bible

Can both fresh water and salt water * flow from the same spring?

Context

9Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. 10Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. 11Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? 12Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù. 13Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.