Native Bible

James 1:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.

James 1:18 in English

James 1:18 · Berean Standard Bible

He chose to give us birth through the word of truth, that we would be a kind of firstfruits of His creation.*

Context

16Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. 17Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. 18Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá. 19Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; 20nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.