Jakọbu 1:17
James 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.
James 1:17 in English
James 1:17 · Berean Standard Bible
Every good and perfect gift is from above, coming down from the Father of the heavenly lights, with whom there is no change or shifting shadow.*
Context
15Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán, a bí ikú. 16Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. 17Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. 18Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá. 19Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.