Isaiah 9:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá; lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú, ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
Isaiah 9:2 in English
Isaiah 9:2 · Berean Standard Bible
The people walking in darkness have seen a great light; on those living in the land of the shadow of death, a light has dawned.*
Context
1Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani. 2Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;
lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,
ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí. 3Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ
gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀
nígbà tí à ń pín ìkógun. 4Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
ìwọ ti fọ́ ọ túútúú
àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,
ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,
ọ̀gọ aninilára wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.