Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere.

Isaiah 7:15 in English

Isaiah 7:15 · Berean Standard Bible

By the time He knows enough to reject evil and choose good, He will be eating curds and honey.

Context

13Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí? 14Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli. 15Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere. 16Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro. 17Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.