Isaiah 65:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wọ́n ń jókòó láàrín ibojì wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀; tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́;
Isaiah 65:4 in English
Isaiah 65:4 · Berean Standard Bible
sitting among the graves, spending nights in secret places, eating the meat of pigs and polluted broth from their bowls.
Context
2Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi síta
sí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle,
tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára,
tí wọ́n sì gbára lé èrò ara wọn 3àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo
lójú ara mi gan an,
wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbà
wọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì; 4wọ́n ń jókòó láàrín ibojì
wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;
tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,
tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́; 5tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,
nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’
Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi
iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó. 6“Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi,
Èmi kì yóò dákẹ́,
ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́;
Èmi yóò san án padà sí àyà wọn
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.