Isaiah 65:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè láti inú ìrora ọkàn yín àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.
Isaiah 65:14 in English
Isaiah 65:14 · Berean Standard Bible
My servants will shout for joy with a glad heart, but you will cry out with a heavy heart and wail with a broken spirit.
Context
12Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà,
àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;
nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.
Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀.
Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi
ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.” 13Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;
ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,
àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,
ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;
àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,
ṣùgbọ́n a ó dójútì yin. 14Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin
láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè
láti inú ìrora ọkàn yín
àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn. 15Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀
fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún;
Olúwa Olódùmarè yóò sì pa yín,
ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun
yóò fún ní orúkọ mìíràn. 16Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà
yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́;
Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà
yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́.
Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé
yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.