Isaiah 64:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Isaiah 64:8 in English
Isaiah 64:8 · Berean Standard Bible
But now, O LORD, You are our Father; we are the clay, and You are the potter; we are all the work of Your hand.
Context
6Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,
gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;
gbogbo wa kákò bí ewé,
àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò. 7Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ
tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;
nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa
ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. 8Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.
Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;
gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 9Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa,
má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.
Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,
nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa. 10Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;
Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.