Isaiah 64:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó tí ó sì mú kí omi ó hó, sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
Isaiah 64:2 in English
Isaiah 64:2 · Berean Standard Bible
as fire kindles the brushwood and causes the water to boil, to make Your name known to Your enemies, so that the nations will tremble at Your presence!
Context
1Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ! 2Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó
tí ó sì mú kí omi ó hó,
sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ
kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ! 3Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,
o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀. 4Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí
kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,
kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,
tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.