Isaiah 62:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.
Isaiah 62:1 in English
Isaiah 62:1 · Berean Standard Bible
For Zion’s sake I will not keep silent, and for Jerusalem’s sake I will not keep still, until her righteousness shines like a bright light, her salvation like a blazing torch.
Context
1Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́,
nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu,
títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,
àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere. 2Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ,
àti gbogbo ọba ògo rẹ
a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn
èyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un. 3Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,
adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.