Isaiah 61:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
Isaiah 61:1 in English
Isaiah 61:1 · Berean Standard Bible
The Spirit of the Lord GOD is on Me, because the LORD has anointed Me to preach good news to the poor. He has sent Me to bind up the brokenhearted, to proclaim liberty to the captives and freedom to the prisoners,*
Context
1Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi
nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí
láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.
Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, 2láti kéde ọdún ojúrere Olúwa
àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, 3àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
irúgbìn Olúwa
láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.