Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa, kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run, dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀, pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.

Isaiah 59:13 in English

Isaiah 59:13 · Berean Standard Bible

rebelling and denying the LORD, turning away from our God, speaking oppression and revolt, conceiving and uttering lies from the heart.

Context

11Gbogbo wa là ń ké bí i beari; àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà. A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré. 12Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá. Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa, àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa, 13ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa, kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run, dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀, pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta. 14Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn, àti ti òdodo dúró lókèèrè; òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà, òdodo kò sì le è wọlé. 15A kò rí òtítọ́ mọ́, àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ pé kò sí ìdájọ́ òdodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.